The death of children – Yorùbá
A translation of Richard Berengarten’s poem ‘The death of children’
by Kọ́lá Túbọ̀sún
The death of children – Yorùbá
Ikú Àwọn Ọmọdé
Ikú àwọn ọmọdé ló mú ìbànújẹ́ bá
Ayé àti ìdájọ́. Kò yẹ ká tún bèèrè ìdí ẹ̀.
Oun tí ìdájọ́ jẹ́, kò sẹ́ni tó yé.
Irú ìfìyàjẹni wo ló le è parí ìjà?
Kò sí irọ́, àwáwí, tàbí ìsápamọ́.
Ikú àwọn ọmọdé ló mú ìbànújẹ́ wá.
Ẹnikẹ́ni tó bá mú ìyàn jíjà wá ń ṣebí
Ẹni tó lè ka èrò àyànmọ́ ni. Bótilẹ̀ jẹ́ pé
A gbọ́dọ̀ búra nípa ìdájọ́, kò yé ẹnìkankan
Bí àyànmọ́ tàbí ayé ṣe ń lọ. Ẹni tó bá ṣègbè
Lẹ́yìn èrò wọn pẹ̀lú àlàyé ń parọ́ ni.
Ikú àwọn ọmọdé ló mú ìbànújẹ́ wá.
Kò yẹ ikú láti rí àwọn èrè púpọ̀ gbà
Láti ọwọ́ àwọn yìí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dáyé, òbí i wọn ń sunkún.
Oun tí ìdájọ́ jẹ́, kò sẹ́ni tó yé.
Ẹ gbé ìtura wá ṣá, àti ìgboyà. Ẹ̀yin àjèjì, ọ̀rẹ́,
Ṣé gbogbo wa kọ́ ni òbí nígbà tí ọmọ bá kú ni?
Oun tí ìdájọ́ jẹ́ báyìí, kò sẹ́ni tó mọ̀.
Ikú àwọn ọmọdé ló mú ìbànújẹ́ wá.
Translated by
Kọ́lá Túbọ̀sún